Egun keegun ni idije boolu alafesegba Governor's Cup 2019, ti o waye lola yi o je leyi to je ara alakale eto lati sayeye odun kan Isejoba Gomina Gboyega Oyetola lofisi.
Atejade kan lati owo alabojuto eto ohun ,Hon Lawrence Babatunde Ayeni, ni Idije ohun leyi ti ajo to n risi idije boolu l'Osun (Osun FA) ati Allantedy Sport promotions se kokari, ni awon omo ile asofin l"abuja lati Osun ninu egbe APC ( Osun APC NASS) s'agbateru re.
Idijo ohun ni o waye ni Oshogbo township stadium lola nibiti gomina Oyetola yoo ti je eni ayesi Pataki.
Ifagagbaga fun ipo keta idije Charity cup yoo ko waye laarin egbe agbaboolu Engineer Adelere Oriolowo FC Iwo ati iko Hon Taiwo Oluga fc Ayedaade laago mewa owuro.
Asekagba idije charity cup yoo waye laarin Ila United Fc ati Asoju rere fc Ifelodun laago mejila osan.
Gege bi atejade ohun ti wi, idije fun ipo lketa Governor's Cup yoo waye laarin egbe agbaboolu Hon Amobi Yinusa fc ati Royal fc Ilobu laago kan osan.
Asekagba idije Governor's cup yoo waye laarin egbe agbaboolu Senator Ajibola Bashiru fc ati Bukoi foundation Fc Ifon laago meta osan.
O wa ro gbogbo eniyan, nipataki julo awon ololufe ise ribiribi ti Gomina Gboyega Oyetola ti gbe se laarin odun kan loofisi lati tu yaya jade lola lo si Oshogbo township stadium fun awon idije wonyi, ati ayesi gomina Oyetola
No comments:
Post a Comment